Categories
Ìròyìn

Ìgbẹ́jọ́ Maina: Fálànà Yawọ Ilé Ẹjọ́, Ó Ní Òun Ṣetán Láti Jẹ́rìí

YBTC News YORÙBÁ—  Agbẹjọ́rò àgbà ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Fẹ́mi Fálànà ní òní ọjọ́bọ̀ ti fa ara rẹ̀ sílẹ̀ láti lọ jẹrìí AbdRasheed Maina, tí ó ń jẹ́jọ́ lọ́wọ́.

Maina ni àwọn àjọ tí ó ń rísí ìlú owó ará ìlú ní póńpó ka onírúurú ẹ̀sùn méjìlá sí lọ́rùn nípa bí ó ṣe ṣe owó ìlú ní kúmakùma, tí ó sì ń káwọ́ pẹ̀yìn rojọ́ ní ilé ẹjọ́ àpapọ̀ Abuja.

Maina ti ó ti fìgbà kan jẹ́ ọ̀gá àwọn tí wọn tọ́jú owó ìfẹ̀yìtì àwọn òṣìṣẹ́ ló ti bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ láti ọjọ́ kinni oṣù yìí. Ó sì ti rọ adájọ́ ọ̀hún láti pàṣẹ kí, Fálànà, àti ènìyàn mẹwàá wá sí ilé ẹjọ́.

Adájọ́ ọ̀hún náà , Okong Abangti pàṣẹ fún agbẹjóeò àgbà nnì, Abubakar Malami, olórí àwọn EFCC nigba kan rí, Magu ati ọ̀gá banki nlá Nàìjíríà, Goodwin Emefiele lati yọjú sílé ẹjọ́.

Nínú gbogbo àwọn tí adájọ́ pàṣẹ fún yìí, Fálànà nikan ni ó yọjú.