Categories
Ìròyìn

Àwọn Àgárá Ọlọ́sà Ti Fọ́ Ilé Ìfowópamọ́ Kan Ní Ọ̀sun

YBTC News YORÙBÁ— Àwọn àgárá ọlọ́sà, alọ-kólóhunkígbe kan ti dìgbò lu ilé ìfowópamọ́ New Generation Bank  ní ìlú Òkukù ní ìpínlẹ̀ Ọ̀sun.

Inú fu àyà fu, ìbẹrù àti ojo ló ti bo gbogbo àwọn ará ìlú Òkukù tí ó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Odõ-Ọ̀tìn ni ìpínlẹ̀ náà, pẹlú bí àwọn ilé Agbébọn se fọ́ ilé ìfowópamọ́ ìlú náà.

Agbẹnusọ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ Ọ̀ṣun , Yẹ́miṣí Ọ̀pálọlá ti jẹ́rí sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wípé lóòótọ ni

Ó sàlàyé wípé ọ̀gá ọlọ́pàá áti àwọn àsọmọgbè rẹ̀ tó kù ti lọ sí ìlú náà níbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi ọ̀hún ti ṣẹlẹ̀