Categories
Ìròyìn

Àwọn Afurasí Agbébọn Ti Jí Àwọn Ọmọ Akẹ́kọ̀ọ́ Àti Olùkọ́ Gbé Ní Ẹdo

YBTC News YORÙBÁ— Ilé iṣẹ́ apàṣẹ ọlọ́pàá tí ìpínlẹ̀ Edo ti jẹ́rí sí bí àwọn afurasí Agbébọn kan ṣe yawọ ilé ẹ́kọ́ Ìmọ̀-ẹ̀rọ Ìkọ́lé kan ní ìpínlẹ̀ Edo, ti wọ́ sì jí àwọn ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ sálọ.

Ilé ẹ̀kọ́ yìí ni ó wà ní ìlú Uromi, ni ìjọba ìbílẹ̀ àríwá- ìyọ oòrùn Esan ni Edo. Àwọn afurasí agbébọn yìí yawọ ilé ẹ̀kọ́ náà ní òru àná ọjọ́’rù tí a sì fi àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ se àwátì.

Alukoro ilé iṣé ọlọ́pàá ìpínlẹ náà, SP. Bello Kontongs no ó fi ìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ fún àwọn oníròyìn ní olú ìlú Benin. Ó sì sàlàyé wípé àwọn ọlọ́pàá tí ń ṣe gbogbo ipá wọn láti ṣe àwárí àwọn òṣìkà náà.

Ó tẹ̀síwájú pé èèyàn mẹ́ta ni wọ́n jìgbé lọ. Nínú wọn ni olùkọ kan tó ń ṣiṣẹ́ nílé ẹ̀kọ́ náà àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjì.