Categories
Ìròyìn

Ìfi Ẹ̀hónúhan: Ọ̀yọ́, Sokoto, Rivers, Àbújá, Èkìtì, Kwara Àti Àwọn Ìpínlẹ̀ Ìyókù Kópa Nínú Ìfi Ẹ̀hónúhàn Jákèjádò Nàíjíríà

YBTC News YORÙBÁ— Ìfi ẹ̀hónúhàn láàrín àkójọpọ̀ ẹgbẹ́ tí ó ń rí sí ìgbàáyé gbádùn àwọn òṣìṣẹ́, NLC, ló ti gba gbogbo orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kan láti àfẹ̀mọ́jú òní.

Jákàjádò Nàíjíríà ni gbogbo àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ti jáde láti ṣe ìfi ẹ̀hónú hàn fún bí àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ńlá Abuja ṣe ń ṣe ìfáárà láti dá ètò ẹ̀kún owó tí ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà buwolu lù láìpẹ́.

Lára àwọn ìpínlẹ̀ tí ó ṣe ìwé ìfi ẹ̀hónú hàn ni a ti rí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Sokoto, Rivers, Èkìtì, Kwara, Abùjá àti òpòlopò ìpínlẹ̀ mìíràn Jákèjádò Nàíjíríà.

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́ ọ, àyípadà sí ètò owó òṣìṣẹ́ tó kéré jù yìí ni yóò mú àdínkù bá owó àwọn òṣìṣẹ́ àti wípé ó lè mú kí àwọn tí wọn ń gbààyàn sísẹ́ má fi ètò tí ìjọba àpapọ̀ buwọ́ lù.