Categories
Ìròyìn

Ìdí Nìyí Tí A Ó Fi Níí Dá Owó Ti A Gbà Lọ́wọ́ Ibori Padà Sí Àpò Delta- Malami

YBTC News YORÙBÁ—  Amòfin àgbà gbogbogbò fun ètò ìdájọ́ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí sàlàyé lẹ́kúnrẹ́rẹ́ ìdí tí àwọn kò ṣe níí dá owó tí àwọn gbà lọ́wọ́ James Ibori Padà sí kòtò asuwon ìpínlẹ Delta.

Malami tẹ̀síwájú nínú àlàyé rè wípé àwọn yóò lo owó náà láti fi ṣe àkànṣe iṣẹ ìjọba àpapọ̀ ni.

Bí ẹ bá rántí pé lánàá òde yìí ni wọn kéde wípé owó tí ó tó £4.2 million ni ìjọba ti fipá gbà padà nínú owó tí Ibori àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní.

Owó náà ni ó ṣeé ṣe kí ó bọ́ sí ọwọ́ ìjọba àpapọ̀ ni bíi ọ̀ṣẹ̀ méjì sí àsìkò yìí. Wọ́n sì ti ya owó náà sọ́tọ̀ fún akanse isẹ́ dída pópónà ọkọ̀ àti títẹ́ afárá.

Nínú àwọn ọ̀nà àti afárá tí owó náà yóò wúlò fún ni: afárá nlá Niger keji àti pópónà márosẹ̀ ọ̀na Èkó sí Ìbàdàn.