Categories
Ìròyìn

Fálànà Bu Ẹnu Àtẹ́ Lù Ìjọba Àpapọ̀, Ó Ní Delta Ni Owó Ibori Tọ́ Sí

YBTC News YORÙBÁ—  Agbẹjọ́rò fún ìjà fún ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn tó gbajúgbajà nnì, Fẹ́mi Fálànà ti kòrò ojú sí ìjoba àpapọ ṣe gbé ẹsẹ̀ lé owó tí wọn gbà lọ́wọ́ James Ibori. Ó ní ìpínlẹ̀ rẹ̀ ló nií, kìí ṣe ìjọba àpapọ̀.

Ó bu ẹnu àtẹ́ lu bí wọ́n ṣe ya owó náà sọ́tọ̀ láti fi ṣe afárá Èkó sí Ìbàdàn àti àwọn àkànṣe iṣẹ́ mìíràn.

Fálànà tẹ̀síwájú pé owó tí wọ́n gbà lọ́wọ́ Gómìnà Plateau nígbà kan rí, Joshua Dariye, ní ìlú Òyìnbó (UK), ó ní wón dá owó náà padà sí ìpínlẹ̀ rẹ̀, Plateau ni.

Bákan náà, ó tẹ̀síwájú pé owó tí wọ́n gbà lọ́wọ́ gómìnà Bayelsa nígbà kan rí, Diepreye Alamieyesigha ní ìlú òyìnbó, ìjọba àpapọ̀ gba owó náà lọ́wọ́ rẹ̀, en sì gbée fún ìjọba ìpínlẹ̀ Bayelsa.