Categories
Ìròyìn

Àjáàbalẹ̀: AGF Abubakar Malami Ti Káṣọ Lójú Eégún Lórí Ọ̀rọ̀ Ìṣèwádí Owó Lọ́dọ̀ Asíwájú Tinúbú

YBTC News YORÙBÁ— Amòfin gbogbogbò nnì tí ó tún jẹ́ mínísítà fún ètò ìdájọ́ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Abubakar Malami (SAN), ti ṣe àlàyé lẹ́kúnrẹ́rẹ́ lórí àhesọ ọ̀rọ̀ wípé ọ́fíìsí òhun ń ṣe ìwádí Asíwájú Tinúbú.

Bí a ò bá gbàgbé, a ó rántí ọ̀rọ̀ àhesọ kan tó ń jà ràinràin láìpé yìí wípé wọn ń ṣe ìwádìí ìṣẹ owó ìlú kúnmọkùnmọ ti Asíwájú Tinúbú.

Malami ni irọ́ tí ó jìnà sí òótọ gbàá ni ọ̀rọ̀ yìí, àwọn kò ṣe ìwádí kankan fún olórí àgbà ẹgbẹ́ APC náà.

Ó tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kìí ṣe ojúṣe àwọn lábẹ́ òfin. Bí àhesọ ọ̀rọ̀ náà bá ti ẹ̀ jẹ́ òótọ́, ojúṣe àwọn tí ó ń rísí ìṣe ìwádìí sí àwọn tó ń Lu owó ìlú ní póńpó ni, EFCC.