Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Ààrẹ Buhari Ti Yan Ahmad Halilu Gẹ́gẹ́ Bí Olùdarí Àgbà fún NASRDA

YBTC News YORÙBÁ— Ààrẹ Buhari ti fi orúkọ arákùnrin Ahmad Halilu ráńsẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùdarí àgbà Titun fún ilé iṣẹ́ tí ó ń rísí ìsèwádí ojú afẹ́fẹ́ sí àwọn ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà tó kalẹ̀ sí Abùjá.

Gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ ààrẹ, Garba shehu se sọ, nígbà tí ó n bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀. Ó sọ wípé ààrẹ se èyí fún ìbámu pẹlú ìwé ofin ilé iṣẹ́ náà.

Títí tí ààrẹ fi yan Halilu gẹ́gẹ́ bí olùdarí àgbà, Halilu jẹ́ ẹnìkan tí ó ti ń darí ilé iṣẹ́ náà gẹgẹ bí olùdarí fìdí hẹẹ́.

Halilu ti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrírí pẹlu bí ó ti ṣe iṣẹ́ ní àwọn ilé iṣẹ́ ńlá bíi ilé iṣẹ́ tí ó ń rísí ètò ìkànìyàn, ilé ìwé ńlá ìjọba tí o dálé ìmọ̀ ẹ́rọ ní Minna àti bẹ bẹ lọ.