Categories
Ìròyìn

Ààbò Ẹ̀sọ́ Ogun Naijiria Pa Àwọn Eesin-ò- kọkú Boko Haram Run, Wo Òǹkà Àwọn Tí Ó Kú

YBTC News YORÙBÁ— Àgbájọ àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Nàìjíríà tí dìgbò lu àwọn eesin- ò- kọkú Boko Haram tí kò dín ni mẹ́talélọ́gbọ̀n ni Chikingudu, wọ́n sì pa gbogbo wọn run ní gàá wọn.

Chikingudu jẹ́ ìletò kan ní ìjọba ìbílẹ̀ Marte ní ìpínlẹ̀ Borno. Abule Missene, Hausari ati Chikungudu   ní àwọn ọmọ ogun yìí tí síná ìbọn fún àwọn Alákatakítí yii.

Bó tilẹ̀ ṣe wípé ọpọ àwọn eesin-ò-kọkú yìí ni àwọn ọmọ ogun fi ìbọn já okùn ẹ̀mí wọn, ẹ̀sọ́ ọmọ ogun méjì ló bá ogun náà lọ.

Ọ̀pọ̀ àwọn ohun èlò ìjà alágbára awọn Boko Haram ni awọn ọmọ ogun bàjẹ́ tí wọn sì gba àwọn ohun èlò ìyókù sí ìkáwọ́n wọn.