Categories
Ìròyìn

Ó Ti Di Ènìyàn Kejì Tí Àrùn Kòkòrò Coronavirus Ti Pa Ní Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà Báyìí

Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti ní àkọsílẹ̀ ẹni kejì tí àrùn kòkòrò apanirun Coronavirus ti pa ní orílẹ̀ èdè yìí báyìí bí àwọn tí wọ́n ní àrùn náà ṣe ń lọ bi ọgọ́fà báyìí.

Mínísítà fún ètò ìlera ní orílẹ̀ èdè yìí, ìyẹn Dókítà Osagie Ehanire ló fi ìdí eléyìí múlẹ̀ lónìí ọjọ́ ajé nígbà tí ó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀.

Osagie wípé aláìsàn náà gbé ẹ̀mí míì ní òpin ọ̀sẹ̀ tí ó kọjá.