Categories
Eré Ìdárayà

Ní Orílẹ̀ Èdè Spain, Wọ́n Sọ Pápá Ìṣeré Real Madrid Di Ibi Ìkó Èròjà Ìtọ́jú Àláàrẹ̀

YBTC News Yorùbá-Ikọ̀ Real Madrid ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé pápá ìṣeré Ikọ̀ ọ̀ún ni wọn ó ma lò fún ibi ìkó èròjà ìtọ́jú aláàrẹ̀ sí báyìí láti fún orílẹ̀ èdè náà ní àǹfààní láti kọjú àìsàn apanirun kòkòrò Coronavirus.

Pápá ìṣeré tí ó gba kọjá ènìyàn lé lọ́nà ẹgbẹ̀rún ọgọ́rin ni wọn ó máa lò fún ibi tí gbogbo ẹrù tí ó bá jẹ́ irànwọ́ tí ó ń wá láti ọwọ́ àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá, pàápàá jùlọ, àwọn irànwọ́ tí ó ń bọ̀ láti ọwọ́ àwọn ilé iṣẹ́ eléré ìdárayá kí ó tó bọ́ sí ọwọ́ àwọn òṣìṣẹ́ Elétò ìlera.