Categories
Ìròyìn

Ní Ìpínlẹ̀ Bauchi, Ó Ti Di Ẹ̀nìkejì Tí ó Ti Lu Gbẹ́dẹ Àrùn Coronavirus Báyìí

YBTC News Yorùbá-Ìwádìí àti àyẹ̀wọ̀ tí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ báyìí wípé ó ti di èèyàn méjì tí ó ti lu gbẹ́dẹ àrùn kòkòrò apanirun Coronavirus ní ìpínlẹ̀ Bauchi báyìí.

Komíṣọ́nà fún ètò ìlera ní ìpínlẹ̀ Bauchi kéde eléyìí nígbà tí ó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ ní ọjọ́ ọjọ́bọ

Ó ní ẹ̀nìkejì náà jẹ́ àgbàlagbà ọmọ ọdún méjìlélọ́gọ́ta

Ìròyìn fìdí rẹẹ̀ múlẹ̀ wípé Gómìnà Ìpínlẹ̀ náà ni ó kọ́kọ́ lu gbẹ́dẹ àrùn náà, léni tí ó jẹ́ wípé ó wà ní ilé ìwòsàn báyìí.