Categories
Ìròyìn

Àwọn Mẹ́fà Kan Tí Wọ́n Lu Gbẹ́dẹ Àrùn Coronavirus Ni Àyẹ̀wọ̀ Fi Hàn Báyìí Wípé Wọn Kò Ní Àrùn Náà Mọ́

YBTC News Yorùbá-Olùbáni Dámọ̀ràn lórí ọ̀rọ̀ ìlera fún gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó, ìyẹn Dókítà Tunde Ajayi ti sọ fún àwọn oníròyìn wípé àwọn mẹ́fà lára àwọn tí ó lu gbẹ́dẹ àrùn kòkòrò apanirun Coronavirus ní ara wọn ti yá báyìí.

Ajayi lórí ẹ̀rọ alátagbà rẹ̀, ìyẹn Twitter ní ọjọ́ ọjọ́bọ sọ pé àwọn mẹ́fà nínú àwọn tí wọ́n ní àrùn náà ni àwọn yóò dá sílẹ̀ láìpẹ́ wípé kí wọ́n máà lọ sí ilé.

Láfikún, Komíṣọ́nà fún ètò ìlera ní ìpínlẹ̀ Èkó, ìyẹn Ọ̀jọ̀gbọ́n Akin Ayobami ní ọjọ́ ọjọ́rú sọ fún àwọn oníròyìn wípé ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó sì ń wà ẹgbẹ̀rún méjì ènìyàn tí ó ṣeéṣe kí wọ́n ti ní àrùn náà látàrí bí wọ́n ṣe ti ṣe alàbá pàdé àwọn tí ó ti ní àrùn náà.