Categories
Eré Ìdárayà

Àwọn Akọ́ni-Mọ̀ọ́gbá àti Agbábọ́ọ̀lú Ikọ̀ Leeds United Gbà Ìdínkù Owó Oṣù Láti Sanwó Àwọn Òṣìṣẹ́ Yòókù

YBTC News Yorùbá-Àwọn agbábọ́ọ̀lú àti Akọ́ni-Mọ̀ọ́gbá Ikọ̀ Leeds United ti gbà láti dín owó oṣù wọn kú nítorí ọjọ́ ọ̀la Ikọ̀ náà àti láti lè san owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́ tí wọn kò ní ǹkan ṣe pẹ̀lú bọ́ọ́lù gbígbá ní ikọ̀ náà.

Díẹ̀ lókù tí Ikọ̀ Leeds ma fi bọ́sí líígì àgbà ọ̀jẹ̀ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì láti ǹkan bi ọdún mẹ́rìndínlógún sẹ́yìn tí wọ́n ti gbá líígì náà gbẹ̀yìn, ṣùgbọ́n tí àrùn kòkòrò apanirun Coronavirus daba rú gbogbo rẹ̀ báyìí.

Ikọ̀ náà sọ wípé owó tí kò wọlé tààrà yóò náà wọn ní ẹ̀gbẹ̀lẹ́gbẹ̀ Mílíọ̀nù ní oṣooṣù.