Categories
Ìròyìn

Ààrẹ Ilé Aṣòfin Àgbà Ilẹ̀ Yìí Rọ Ìjọba Àpapọ̀ Láti Pèsè Ètò Irànwọ́ Fún Àwọn Ọmọ Nàìjíríà Bí Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ṣe ń Jókòó Sílé Báyìí

YBTC News Yorùbá-Ààrẹ ilé Aṣòfin Àgbà ilẹ̀ yìí, ìyẹn Aṣòfin Ahmad Lawan ti ké sí ìjọba àpapọ̀ ilẹ̀ yìí wípé kí ó yára pèsè ètò irànwọ́ fún àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí tí ó jẹ́ wípé jíjòkò sílé yóò ṣe àkóbá ńláńlá fún iṣẹ́ òòjọ́ wọn.

Lawan nínú ọ̀rọ̀ tí ó fi léde láti ẹnu agbẹnusọ rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn, ìyẹn Ezrel Tàbí owó bẹ̀bẹ̀ fún irànwọ́ náà lẹ́yìn ìpàdé tí ó wáyé láàárín àwọn aláṣẹ ilé Aṣòfin náà, àwọn Mínísítà àti àwọn olórí ilé iṣẹ́ ìjọba ní ọjọ́ ọjọ́rú ní ìlú Abuja.

Ààrẹ náà sọ wípé yàtọ̀ sí kí àwọn ọlọ́jà má tajú àti kí àwọn ènìyàn gbélé wọn, ó yẹ kí ètò irànwọ́ wà fún àwọn aláìní, láti ra oúnjẹ àti èròjà ètò ìlera.