Categories
Ìròyìn

Olórí Ilé Iṣẹ́ Ààrẹ Buhari, Kyari, Lu Gbẹ́dẹ Àrùn Kòkòrò Coronavirus

YBTC News Yoruba—Olórí ilé iṣẹ́ Ààrẹ ti Ààrẹ Muhammadu Buhari, ìyẹn Abba Kyari ni ìròyìn ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé ó ti lu gbẹ́dẹ àrùn kòkòrò apanirun Coronavirus báyìí.

Alamí kan ní ilé iṣẹ́ tí ó ń rí sí ètò ìlera ní orílẹ̀ èdè yìí sọ fún àwọn oníròyìn wípé Kyari tí ó padà sí orílẹ̀ èdè yìí láìpẹ́ yìí láti orílẹ̀ èdè Jamaní ni àyẹ̀wọ̀ ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé ó ti lu gbẹ́dẹ àrùn náà.

Alamí náà sọ pé wọ́n ṣe àyẹ̀wọ̀ fún Ààrẹ Buhari, àyẹ̀wọ̀ náà sì fi hàn wípé Ààrẹ kọ í tíì lu gbẹ́dẹ àrùn náà, ṣùgbọ́n wọ́n tún ma ṣe àyẹ̀wọ̀ fún Buhari lẹ́ẹ̀kan si lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀.