YBTC News Yorùbá-Ọmọ ogún ọdún kan rèé ni ó ti kó sí akóló àwọn Ọlọ́pàá báyìí látàrí ẹ̀sùn ìjábalé ọmọ ọdún mẹ́rin kan, tí ó ní ọ̀rẹ́ òun ni.
Arákùnrin náà tí ó pè ní Ọ̀gbẹ́ni Isaac Boniface ni ó ti jábalé ọmọ obìnrin ọmọ ọdún mẹ́rin ní àdúgbò Danwoh ní gúúsù Jos ní ìpínlẹ̀ Plateau.
Boniface tí ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé lóòótọ́ ni òun jábalé ọmọdébìnrin ọmọ ọdún mẹ́rin náà, sọ pé ọ̀rẹ́ ni òun àti ọmọ náà.