Categories
Ìròyìn

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó Kéde Àwọn Ènìyàn Mẹ́rin Ti Titun Tí ó Ní Àrùn Coronavirus

YBTC News Yorùbá-Komíṣọ́nà fún ètò ìlera ní ìpínlẹ̀ Èkó, ìyẹn Ọ̀jọ̀gbọ́n Akin Ayobami tí sọ pé àwọn ènìyàn mẹ́rin tuntun míràn ti ní àrùn kòkòrò apanirun Coronavirus ní ìpínlẹ̀ Èkó báyìí.

Ní ọjọ́ ọjọ́rú nígbà tí ó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ lórí oun tuntun tí ó ti ń ṣẹlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ àrùn kòkòrò corona, ó ní àwọn mẹ́rin tuntun náà jẹ́ àlékún àwọn mẹ́fà tí ó ti wà nílẹ̀ báyìí.

Pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, orílẹ̀ èdè Nàìjíríà wá ti ní àkọsílẹ̀ àrùn kòrónà méjìlá báyìí. Mọ́kànlá ní ìpínlẹ̀ Èkó, Ẹyọkan ní ìpínlẹ̀ Ekiti. Àyẹ̀wò padà fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé ìkan kòní àrùn náà lára mọ́.