Categories
Eré Ìdárayà

Ìdí Rèé Tí Mofi Fi Ikọ̀ Agbábọ́ọ̀lù Arsenal Sílẹ̀ – Ajayi Lahùn

YBTC News Yorùbá-Agbábọ́ọ̀lù nípò ẹ̀hìn fún ikọ̀ West Brom ní orílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì, ìyẹn Semi Ajayi ti ṣàlàyé fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ìdí tí òun fi fi Ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lú Arsenal sílẹ̀ lọ sí Ikọ̀ míràn lẹ́yìn sáà igbábọ́ọ́lù méjì péré.

Ajayi sọ pé òun ń wá Ikọ̀ agbábọ́ọ̀lú tí ó jẹ́ wípé òun ma máa gbá bọ́ọ́lù déédéé ni ó fàá kí òun fi fi Ikọ̀ agbábọ́ọ̀lú náà sílẹ̀ lẹ́yìn ọdún méjì lọ sì Ikọ̀ agbábọ́ọ̀lú míràn.

Ajayi kúrò ní ikọ̀ Arsenal lọ sí Ikọ̀ Cardiff City ní 2015. Ó lo sáà igbábọ́ọ́lù kan ní ikọ̀ Charlton Athletic kí ó tó darapọ̀ mọ́ Ikọ̀ Arsenal.