Categories
Eré Ìdárayà

Akọ́ni-Mọ̀ọ́gbá Ikọ̀ Agbábọ́ọ̀lù Ti Orílẹ̀ Èdè Turkey Ti Sọ Burúkú Ọ̀rọ̀ Sí Ikọ̀ Tí ó Jáwe Gbéléẹ Lé Mikel Obi Lọ́wọ́

YBTC News Yorùbá-Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí fún ìgbìmọ̀ aláṣẹ ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáwé gbéléẹ lé Mikel Obi lọ́wọ́ tí ó tún jẹ́ Akọ́ni-Mọ̀ọ́gbá fún ikọ̀ agbábọ́ọ̀lú orílẹ̀ èdè Turkey ìyẹn Ozkan Sumer ti sọ ọ̀rọ̀ burúkú sí Ikọ̀ Trabzonspor lórí bí Ikọ̀ náà ṣe ní kí Mikel Obi lọ rọ́kúnlé.

Bákannáà ni Sumer sọ̀rọ̀ burúkú sí àjọ tí ó ń rí sí ọ̀rọ̀ bọ́ọ́lù gbígbá ní orílẹ̀ èdè Turkey, ìyẹn Turkish Football Federation lórí bí wọ́n ṣe kùnà láti dá bọ́ọ́lù gbígbá dúró lásìkò yìí ní orílẹ̀ èdè náà.

Ó mú lele wípé àjọ tí ó rí sí ọ̀rọ̀ bọ́ọ́lù àfẹsẹ̀gbá ní orílẹ̀ èdè náà kọ́ni ètò àti ìlànà tí ó yanrantí fún ètò ìlera àwọn agbábọ́ọ̀lú ní orílẹ̀ èdè náà.