Categories
Ìròyìn

Mínísítà Fún Ètò Ìlera Kó Àrùn Kòkòrò Coronavirus Ní Orílẹ̀ Èdè Gẹ̀ẹ́sì

YBTC News Yorùbá-Mínísítà fún ètò ìlera ní orílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì, ìyẹn arábìnrin Nadine Dorries ti kó àrùn kòkòrò apanirun Coronavirus. Ó sọ ọ̀rọ̀ yìí ní ọjọ́ ìṣẹ́gun, léyìí tí ó sì fàá kí àwọn ènìyàn máa rò ó wí pé àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba lè ti fara kó àrùn kòkòrò náà.

Mínísítà náà sọ̀rọ̀ wípé òun lè fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé òun tilu gbẹ́dẹ àrùn náà, bẹ́ẹ̀ ni òun ti wà ní abẹ́ àyẹ̀wọ̀ aládani báyìí.

Àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera ní orílẹ̀ èdè náà ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí láti mọ ibi tí Mínísítà náà ti lè kó àrùn náà. Lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí, ènìyàn mẹ́fà ni ó ti gbé ẹ̀mí mì látàrí àrùn kòkòrò apanirun náà.