Categories
Ìròyìn

Makinde Wọ Aṣọ Àmọ̀tẹ́kùn Láti Buwọ́lu Ìwé Àbádòfin Àmọ̀tẹ́kùn

YBTC News Yorùbá-Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ìyẹn Seyi Makinde ní ọjọ́ ìṣẹ́gun wọ aṣọ aláwọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn láti buwọ́lu ìwé òfin tí ó ma ṣe ìdásílẹ̀ Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò àgbègbè ní ìpínlẹ̀ náà, léyìí tí ó ma ṣe ìdásílẹ̀ Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Àmọ̀tẹ́kùn tí àwọn gómìnà ìwọ oòrùn gúúsù ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ ní àìpé yìí.

Ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ọjọ́ kẹta oṣù kẹta ọdún yìí ṣe òfin ìdásílẹ̀ ẹ̀ṣọ́ aláàbò àgbègbè ní ìpínlẹ̀ náà láti fi òfin kín ìdásílẹ̀ Àmọ̀tẹ́kùn lẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì fi ṣọwọ́ sí Gómìnà náà láti buwọ́lu kí òfin náà lè di òfin tí ó múlẹ̀.

Gómìnà Makinde tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà láti ibi ìpàdé ìdókoòwò kan ní orílẹ̀ èdè náà buwọ́lu òfin náà ní ọjọ́ ìṣẹ́gun léyìí tí ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin ìpínlẹ̀ fi ṣọwọ́ si.