Categories
Ìròyìn

Lórí Àrùn Kòkòrò Coronavirus, Líígì Orílẹ̀ Èdè Spain Yóò Ma Wáyé Láìsí Èrò Ìwòran

YBTC News Yorùbá-Líígì àgbà ọ̀jẹ̀ orílẹ̀ èdè Spain àti líígì tí ó tẹ̀le ni ìròyìn ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé yóò ma wáyé fún ó kéré tán ọ̀sẹ̀ méjì látàrí Ìtànkálẹ̀ Àrùn kòkòrò apanirun Coronavirus tí ó yọ gbogbo ayé láàmú báyìí.

Ìgbésẹ̀ náà wáyé lẹ́yìn tí àwọn ìgbìmọ̀ Aláṣẹ fún gbogbo eré ìdárayá ní orílẹ̀ èdè Spain fẹnu kò láti jẹ́ kí gbogbo eré ìdárayá máa wáyé láìsí èrò iwòran láti dé na Ìtànkálẹ̀ Àrùn náà.