Categories
Ìròyìn

Báyìí Ni Aṣe Léè Emir Àná Kúrò Láàfin Ní Ìpínlẹ̀ Kano – Agbẹnusọ Gómìnà

YBTC News Yorùbá-Amúgbálẹ́ẹ̀gbẹ́ lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn fún gómìnà Abdullahi Ganduje ti ìpínlẹ̀ Kano, ìyẹn Salihu Yakasai sọ wípé Emir tẹ́lẹ̀ rìí fún ìpínlẹ̀ Kano, ìyẹn Muhammadu Sanusi II tí Gómìnà Ìpínlẹ̀ Kano ṣẹ̀ rọ̀ lóyè láìpẹ́ yìí kò fẹ́ kúrò láàfin kódà lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jẹ́ kí ó mọ̀ wípé wọ́n ti rọ̀ lóyè ní ọjọ́ ajé.

Yakasai sọ pé ìjọba ìpínlẹ̀ náà ní láti kó àwọn Ọlọ́pàá dìgbòlùjà lọ sí ààfin láti sì ń jáde kúrò láàfin. Agbẹnusọ fún gómìnà náà sọ̀rọ̀ yìí ní orí ẹ̀rọ amóhùn-mọ́wòrán kan ní ọjọ́ ìṣẹ́gun.

Ó ní tá ní Emir tẹ́lẹ̀ rìí náà pọ́n ara rẹ̀ lé ní, tí ó sì kúrò láàfin lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí wọ́n ti fi tó o létí, kò ní di ẹni tí àwọn Ọlọ́pàá dìgbòlùjà ń sìn jáde kúrò láàfin.