Categories
Eré Ìdárayà

Àwọn Agbábọ́ọ̀lù Ikọ̀ Arsenal Wà Ní Ìyàrá Àyẹ̀wọ̀ Lórí Ọ̀rọ̀ Coronavirus, Wọ́n Sún Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Síwájú

YBTC News Yorùbá-Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tí ó yẹ kí Ikọ̀ Arsenal ti orílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì gbá ní ọjọ́ ọjọ́rú ní wọ́n ti sún síwájú látàrí bí gbogbo agbábọ́ọ̀lú Ikọ̀ náà ṣe wà ní ìyàrá àyẹ̀wọ̀ fún àrùn kòkòrò apanirun Coronavirus.

Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n ma sún ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ síwájú lórí lẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì láti ìgbà tí àrùn náà tí ń tàn káàkiri àgbáyé.

Ikọ̀ Arsenal ní àwọn agbábọ́ọ̀lú Ikọ̀ náà àti òṣìṣẹ́ mẹ́rin ni wọ́n wà ní ìyàrá àyẹ̀wọ̀ báyìí lẹ́yìn ìgbà ti ṣe alábàpàdé pẹ̀lú bàbá olówó tí ó ni Ikọ̀ Olympiakoa, lẹ́ni tí àyẹ̀wò ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé ó ti ní àrùn náà.