Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Àádọ́rin Ènìyàn Lu Jàm̀bá Bí Ilé Àyẹ̀wọ̀ Ìlera Fún Àwọn Tí Wọ́n Ní Àrùn Coronavirus Ṣe Dàwó Lulẹ̀ Ní Orílẹ̀ Èdè China

YBTC News Yoruba—Bí àádọ́rin ènìyàn ni ó ti rá sínú pàlàpálá ilé àyẹ̀wọ̀ tí wọ́n yà sọ́tọ̀ láti máa fi àwọn ènìyàn tí wọ́n ní àrùn Coronavirus ní orílẹ̀ èdè China sí ṣe dàwó lulẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ àbàmẹ́ta.

Bí èèyàn méjìdínlógójì ni àwọn òṣìṣẹ́ adóòlà ẹ̀mí ti rí yọ báyìí níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ilé náà jẹ́ ilé ìgbafẹ́ kan tí ó jẹ́ oníyàrá ọgọ́rin tí ó wà ní Xinjia ní ìlú etí-òkun Quanzhou, gẹ́gẹ́ bí ìjọba ìbílẹ̀ náà ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀.

Ó jọ bí ẹ ni wípé ilẹ̀ rírì ni ó fa ìdí tí ilé náà fi wó lulẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkíyèsí ṣe fi hàn nínú fọ́nrán tí ó wà ní orí ẹ̀rọ ayélujára ilé iṣẹ́ ìròyìn kan ní ilẹ́ òkèèrè ìyẹn Weibo.

Àádọ́rin Ènìyàn Lu Jàm̀bá Bí Ilé Àyẹ̀wọ̀ Ìlera Fún Àwọn Tí Wọ́n Ní Àrùn Coronavirus Ṣe Dàwó Lulẹ̀ Ní Orílẹ̀ Èdè China

Bí àádọ́rin ènìyàn ni ó ti rá sínú pàlàpálá ilé àyẹ̀wọ̀ tí wọ́n yà sọ́tọ̀ láti máa fi àwọn ènìyàn tí wọ́n ní àrùn Coronavirus ní orílẹ̀ èdè China sí ṣe dàwó lulẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ àbàmẹ́ta.

Bí èèyàn méjìdínlógójì ni àwọn òṣìṣẹ́ adóòlà ẹ̀mí ti rí yọ báyìí níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ilé náà jẹ́ ilé ìgbafẹ́ kan tí ó jẹ́ oníyàrá ọgọ́rin tí ó wà ní Xinjia ní ìlú etí-òkun Quanzhou, gẹ́gẹ́ bí ìjọba ìbílẹ̀ náà ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀.

Ó jọ bí ẹ ni wípé ilẹ̀ rírì ni ó fa ìdí tí ilé náà fi wó lulẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkíyèsí ṣe fi hàn nínú fọ́nrán tí ó wà ní orí ẹ̀rọ ayélujára ilé iṣẹ́ ìròyìn kan ní ilẹ́ òkèèrè ìyẹn Weibo.

Títí di àsìkò yìí, àwọn aláṣẹ orílẹ̀ èdè China kò ì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ bóyá ènìyàn kankan ti gbé ẹ̀mí míì látàrí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.