Categories
Ìròyìn

Lórí Kòkòrò Apanirun Coronavirus: Ọmọ Ilẹ̀ Ìtàló Tí ó Wà Ní Abẹ́ Àyẹ̀wọ̀ Báyìí Ń Ro Àròkàn

YBTC News Yorùbá-Komíṣọ́nà fún ètò ìlera ní ìpínlẹ̀ Èkó, Ọ̀jọ̀gbọ́n Akin Ayobami ti sọ ní ọjọ́ ẹtì wípé ọmọ orílẹ̀ èdè Ìtàló tíó wà ní abẹ́ àyẹ̀wọ̀ ní ilé ìwòsàn ní ìpínlẹ̀ Èkó ń ro àròkàn.

Nígbà tí Komíṣọ́nà náà ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ lórí oun tuntun tí ó ti ṣẹlẹ̀ lórí àrùn náà, ó ní ọkùnrin náà ti wà ní abẹ́ àyẹ̀wọ̀ fún ọ̀sẹ̀ kan, tí ó sì ní lo òògùn daada ṣùgbọ́n àwọn yóò da sílẹ̀ nígbà tí àwọn bá ri wípé ìtúsílẹ̀ rẹ̀ kòní ṣe àkóbá fún àwùjọ.

Láfikún, Komíṣọ́nà náà sọ wípé àwọn arìnrìn-àjò méjì tí wọ́n bá ọmọ ilẹ̀ Ìtàló náà wọ ọkọ̀ òfurufú pọ̀ ṣì di àwátì báyìí