Categories
Ìròyìn

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ondo, Èkó, Ogun, Osun àti Oyo Buwọ́lu Ìwé Àbádòfin Àmọ̀tẹ́kùn Ní Ọjọ́ Ìṣẹ́gun

YBTC News Yorùbá-Olórí ọmọ ẹgbẹ́ tó pọ̀ jùlọ nílé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ondo, ìyẹn Jamiu Maito ni ó pèpè fún ìdásílẹ̀ ẹ̀ṣọ́ aláàbò fún ìpínlẹ̀ ọ̀ún àti àbá fún ìdásílẹ̀ ẹ̀ṣọ́ aláàbò Àmọ̀tẹ́kùn ní ìpínlẹ̀ náà tí aṣòfin Favour Towemimo sì ṣègbè fún ìpè náà.

Gẹ́gẹ́ bí àbádòfin náà ṣe lọ, Gómìnà ìpínlẹ̀ náà ni yóò ma yan alága fún ìgbìmọ̀ ẹ̀sọ́ aláàbò náà nítorí ó pọn dandan fún ẹṣọ aláàbò náà láti ní olórí.

Gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ fún ilé Aṣòfin náà ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀, ó ní ìbuwọ́lu òfin náà jẹ́ ìgbésẹ̀ tó lààmìlaka nínú ètò òṣèlú.

Bákannáà ní ọ̀bọ ṣe ṣe orí ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Èkó, Ogun àti Osun.