Categories
Eré Ìdárayà

Gbígbá Bọ́ọ́lù Sáwọ̀n Fún Ikọ̀ Manchester United, Jẹ́ Wípé Àlá Mi Wá Sí Ìmúṣẹ

YBTC News Yorùbá-Agbábọ́ọ̀lù nípò iwájú fún ikọ̀ Manchester United, Odion Ighalo ti sọ wípé gbígbá bọ́ọ́lù sáwọ̀n fún ikọ̀ náà jẹ́ wípé àlá òun láti kékeré wá sí ìmúṣẹ.

Ní oṣù kìíní ọdún yìí ni Ikọ̀ Manchester United tọwọ́ Ighalo fún àdéhùn olóṣù mẹ́fà láti Ikọ̀ tí ó wà tẹ́lẹ̀ ní orílẹ̀ èdè China.

Ighalo gbá bọ́ọ́lù fún ikọ̀ Manchester United ní ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn tí agbábọ́ọ̀lú ní ipò iwájú Ikọ̀ náà ní ìfarapa ránpẹ́, ìyẹn Anthony Martial, léni tí wọ́n tí forúkọ rẹ̀ sílẹ̀ wípé ó ma kópa nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà.