Categories
Ìṣẹjúkan àti Àbọ̀

Àwọn Ọ̀nà Tí a Lè Gbà Dènà Ìtànkálẹ̀ Àrùn Coronavirus Ní Àwùjọ Wa Rèé

Àwọn Ọ̀nà Tí a Lè Gbà Dènà Ìtànkálẹ̀ Àrùn Coronavirus Ní Àwùjọ Wa Rèé

Kí a ma fọ ọwọ́ wa dáadáa pẹ̀lú omi ẹnu ẹ̀rọ tí ó ń jáde tààrà. Kí a sì ma lo ọṣẹ kòkòrò tí ó ní ọtí nínú láti ma fi fọwọ́ wa.

Kí o máa lo ìbọ̀wọ́ kan nígbà kan, tí ó bá ti dọ̀tí, o gbọ́dọ̀ pàrọ̀ rẹ̀ ní kíá kíá.

Kí a ma fi ìgúnpá wa bo imú tàbí ẹnu nígbàkigbà tí a bá wúkọ́ tàbí sín. A lè lo ìwé fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí a mọ̀ sí tissue, tí a sì ri dájú wípé a sọ́ sí ilé ilẹ̀ níbi tí ẹnìkankan kọ́ni ṣe alàbá pàdé rẹ̀.

Yàgò fún fífi ọwọ́ lásán nu ojú, àágùn, imú tàbí ro ẹnu, àyàfi tí o bá fọwọ́ rẹ kí ó mọ́ dáadáa.

Fi ààyè òdiwọ̀n mítà kan àti àbọ̀ sílẹ̀ láàrin ìwọ àti ẹnikẹ́ni tí ó ń wúkọ́ ní agbègbè rẹ tàbí tí ó ń sín.

Tó bá jẹ́ wípé o ti rìnrìn àjò lọ sí orílẹ̀ èdè tí ó ní àrùn náà láàárín ọjọ́ mẹ́rìnlá sí àsìkò yìí, tí o wá bẹ̀rẹ̀ sí ní húkọ́, ní ibà àti àwọn àpẹẹrẹ mìíràn, ó ṣe pàtàkì fún ọ láti ké pe NCDC (0800-970000-10) kí o tó lọ sí ilé ìwòsàn.

Yẹra kúrò níbi àti máa dàpọ̀ Mọ́ àwọn ènìyàn tí ó bá jẹ́ wípé o ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti ìrìnàjò lọ sí orílẹ̀ èdè tí àrùn náà wà

YBTC News Yorùbá