Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Ẹṣọ́ra Fún Ìròyìn Ẹlẹ́jẹ̀ Lórí Ẹ̀rọ Alátagbà – Mínísítà Fún Ètò Ìlera Ṣe Ìkìlọ̀

YBTC News Yoruba—Lẹ́yìn ìkéde àrùn apànìyàn tí ó gbalẹ̀ kan ní àgbáyé, ìyẹn Coronavirus ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Mínísítà fún ètò ìlera ní orílẹ̀ èdè yìí, ìyẹn Dókítà Osagie Ehanire ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Nàìjíríà níbi mímagbé Ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ kiri lóri ẹ̀rọ alátagbà, ìyẹn social media.

Mínísítà náà sọ̀rọ̀ yìí nígbà tí ó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní ọjọ́ ẹtì ní olú ìlú wa ní Abuja.

Mínísítà náà ní àti awakọ̀ àti gbogbo òṣìṣẹ́ ètò ìlera tí wọ́n ṣe àyẹ̀wọ̀ fún ará ilẹ̀ òkèèrè tí ó kó àrùn náà wọ orílẹ̀ èdè yìí ní wọ́n dáàbò bo ara wọn.