Categories
Ìròyìn

Buhari ÓÒ, Ẹ Má Jẹ́kí Bàálù Kankan Wá Sí Orílẹ̀ Èdè Yìí Láti Orílẹ̀ Èdè Tí Coronavirus Bá ń Yọ Lẹ́nu – Atiku

YBTC News Yoruba—Igbá-kejì Ààrẹ ní orílẹ̀ èdè yìí nígbà kan rí, tí ó tún jẹ́ òǹdíje dupò Ààrẹ lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP), ìyẹn Atiku Abubakar ti gba Ààrẹ Muhammadu Buhari lámọ̀ràn lórí ọ̀rọ̀ Coronavirus tí ó wọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lẹ́nu lọ́wọ́ lọ́wọ́ yìí.

Atiku nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé kí Ààrẹ Muhammadu Buhari tilẹ̀kùn ibodè orílẹ̀ èdè yìí mọ́ orílẹ̀ èdè tí àrùn náà ń bá jà. Ó ní kí ilẹ̀ Nàìjíríà kojú ìṣẹ̀lẹ̀ náà bí ó ṣe kojú Ebola.

Ó sọ ọ̀rọ̀ yìí ló rí ẹ̀rọ alátagbà rẹ̀, ìyẹn Facebook, ó ní tí orílẹ̀ èdè yìí bálè ti ilẹ̀kùn ibodè rẹ̀ fún ọ̀rọ̀ ajé, ó yẹ kí ó lè ti ilẹ̀kùn mọ́ orílẹ̀ èdè kórílẹ̀ èdè tí àrùn Coronavirus ń bá jà.