Categories
Eré Ìdárayà

Agbábọ́ọ̀lú Ọmọ Nàìjíríà Kan Ti Kó Coronavirus Ní Orílẹ̀ Èdè Ìtàló

YBTC News Yoruba—Agbábọ́ọ̀lù kan ní líígì kẹta ní orílẹ̀ èdè Ìtàló ni ìròyìn ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé ó kó àrùn Coronavirus báyìí.

A gbọ́ wípé òun ni ó jẹ́ agbábọ́ọ̀lù àkọ́kọ́ tí ó ma kó àrùn náà ní orílẹ̀ èdè aláwọ̀ funfun láti ìgbà tí àrùn náà tí ń tàn káàkiri àgbáyé.

Gẹ́gẹ́ bí ilé iṣẹ́ ìròyìn orílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀, ó ní agbábọ́ọ̀lú náà jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti Ìtàló. Wọ́n sì pe orúkọ agbábọ́ọ̀lú náà ní Paul Akpan Udon.

Udoh tí ó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlélógún ń gbá bọ́ọ́lù jẹun ní ikọ̀ Pianese ní líígì kẹta ní orílẹ̀ èdè Ìtàló. A gbọ́ wípé ọjọ́ ọjọ́bọ ní Àyẹ̀wọ̀ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé Udor ní àrùn náà, tí wọ́n sì fi sí ìyàrá ìtọ́jú báyìí.