YBTC News Yorùbá-Ikọ̀ Inter Milan ti orílẹ̀ èdè Ìtàló yóò gbá ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn pẹlu Ikọ̀ Ludogrets ní abẹ́lé nínú ìdíje Ọ̀gá-Ọ̀gá, ìyẹn Europa League látàrí Àtànkákẹ̀ àrùn Coronavirus tí ó ń jà ràìnràín káàkiri àgbáyé.
Àrùn náà ti kó àwọn aláṣẹ bọ́ọ́lù àfẹsẹ̀gbá àti ìjọba orílẹ̀ èdè Ìtàló náà sí hílàhílo, lèyí tí ó sì mú kí àwọn aláṣẹ náà pàṣẹ láti sún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ nínú líígì náà àti èyí tí ó tẹ̀le ìyẹn seria A and B.
Ní òru ọjọ́ kan péré, èèyàn ọgbọ́n ní wọ́n fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé wọ́n kó àrùn náà, nígbà tí èèyàn mọ́kànlá ti gbẹ́mìí mì.