Categories
Ìròyìn

Kòsí Àyẹ̀wọ̀ Tó Péye Mí Pápákọ̀ Òfurufú Wa Fún Èèyàn Tí Ó Ní Àrùn Coronavirus Virus – Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àgbà

YBTC News Yorùbá-Ilé Aṣòfin Àgbà Ilẹ̀ yìí ní ọjọ́ ọjọ́bọ bu ẹnu àtẹ lu ẹ̀ka tó ń rí sí ètò ìlera ní orílẹ̀ èdè yìí lóri bí ẹ̀ka náà ṣe kùnà láti dènà àrùn Coronavirus pé kí ó má wọ orílẹ̀ èdè yìí.

Ilé Aṣòfin Àgbà náà wá rọ ìgbìmọ̀ ilé Aṣòfin náà lórí ètò ìlera wípé kí ó fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ka tí ó ń rí sí ètò ìlera ní orílẹ̀ èdè yìí láti máa ṣe àyẹ̀wọ̀ tó péye fún àwọn tí wọ́n ń wọ orílẹ̀ èdè yìí láti pápákọ̀ òfurufú àti ojú omi wa daadaa.

Ààrẹ ilé Aṣòfin náà, ìyẹn Ahmed Lawan sọ ọ̀rọ̀ yìí nígbà tí igbá kejì ọmọ ẹgbẹ́ tó pọ̀ jùlọ ní ilé Aṣòfin náà, ìyẹn Ajayi Boroffice pe àkíyèsí ilé Aṣòfin náà lóri bí ẹ̀ka ètò ìlera ilẹ̀ yìí ṣe fi ọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú Àyẹ̀wọ̀ náà.