Categories
Eré Ìdárayà

Nemanja Metic Yóò Fi Ikọ̀ Manchester United Sílẹ̀ Lópin Sáà Igbábọ́ọ́lù Yìí

YBTC News Yorùbá-Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀, gbajúgbajà ọmọ ilẹ̀ Serbia tí ó ń gbá bọ́ọ́lù jẹun ní ikọ̀ Manchester United ní orílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì yóò fi Ikọ̀ náà sílẹ̀ lópin sáà igbábọ́ọ́lù yìí nígbà tí àdéhùn rẹ̀ pẹ̀lú Ikọ̀ náà yóò dópin.

Metic kò ráyè gbá bọ́ọ́lù dáadáa lábẹ́ Akọ́ni-Mọ̀ọ́gbá Ikọ̀ Manchester United, ìyẹn Gunnar Solskjaer, ní èyí tí ó jẹ́ wípé ìgbà ẹ̀meejìlélógún ni ó ti kópa nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ní sáà yìí.

Lóòótọ́ ni ó ti kópa nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ mẹ́ta tí ó gbẹ̀yìn tí Ikọ̀ Manchester United ti kópa níbẹ̀ nínú gbogbo ìdíje tí Ikọ̀ náà ń kó pa níbẹ̀ lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí ṣùgbọ́n Ìròyìn fìdí rẹẹ̀ múlẹ̀ wípé ó ń lọ.