Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Ilé Ẹjọ́ Sọ Olisa Metuh Sí Ẹ̀wọ̀n Ọdún Méje

YBTC News Yorùbá-Agbẹnusọ fún ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP) tẹ́lẹ̀ rí, ìyẹn Olisa Metuh ni ilé ẹjọ́ gíga ti ìjọba àpapọ̀ tí ó wà ní ìlú Abuja ti sọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún méje báyìí lórí ẹ̀sùn ìṣe owó ìlú mákumàku ṣáájú ìdìbò ọdún 2015 ní èyí tí ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ fìdí rẹ mi.

Adájọ́ Okon Abang nínú Ìdájọ́ rẹ̀ sọ pé Metuh jẹ̀bi ẹ̀sùn méje tí wọ́n fi kàn án ní èyí tí ẹ̀sùn ayédèrú ìwé ẹ̀rí ìsanwó wọ báńkì wà nínú rẹ̀.

Ẹ̀sùn tí ó tún pẹ̀lú náà ni bí ó ṣe gba Mílíọ̀nù lọ́nà okòó méjì jáde láti ọ́fìsì olùgbani lámọ̀nràn tẹ́lẹ̀ rí ní oṣù kankànlá ọdún 2014, tí ó sì lo owó náà fún ọ̀rọ̀ òṣèlú àti àpò ara rẹ̀.

Ilé ẹjọ́ náà tún dá Metuh lẹ́bi wípé ó ṣe ìdúnnadúrà pẹ̀lú Mílíọ̀nù méjì owó ilẹ̀ òkèèrè ìyẹn 2M Dollars láì gba ọ̀nà ẹ̀tọ́