Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Kòsí Àní Àní, Ó Di Dandan Kí Àmọ̀tẹ́kùn Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin – Obasa àti Gani Adams Sọ̀rọ̀

YBTC News Yorùbá-Ààrẹ Ọ̀nà Kankafò Fún Gbogbo Yorùbá, Iba Gani Adams àti Agbẹnusọ fún ilé Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó, Ọ̀gbẹ́ni Mudashiru Obasa sọ ní ọjọ́ ajé wípé kò sí àní àní, Àmọ̀tẹ́kùn yóò fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin gẹ́gẹ́ bi Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò ní ìpínlẹ̀ Èkó àti káàkiri gbogbo iwọ́ oòrùn gúúsù orílẹ̀ èdè yìí.

Àwọn méjèèjì sọ̀rọ̀ yìí níbi ìpàdé ìta gbangba kan tí ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó ṣe àgbékalẹ̀ láti gbọ́ tẹnu àwọn ènìyàn ní lẹ́gbẹ́ lẹ́gbẹ́ àti lọ́gbà lọ́gbà ní ìpínlẹ̀ Èkó.

Lára àwọn ẹ̀ka kàn ǹ kan tí aṣojú wà níbẹ̀ ni ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC), Ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP), Ẹgbẹ́ Hausawa, Ẹgbẹ́ àwọn ọmọ lẹ́yìn Krìstì, Ẹgbẹ́ àjà fún ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn, Ẹgbẹ́ fijilanté àti àwọn mìíràn.