Categories
Ìròyìn

Ibà Ìrẹ̀lẹ̀ (Lassa Fever) Tuntun Ṣẹ́yọ Ní Ìpínlẹ̀ Kaduna

YBTC News Yoruba—Komíṣọ́nà fún ètò ìlera ní ìpínlẹ̀ Kaduna, ìyẹn Dókítà Amina Mohammed-Baloni ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní ọjọ́ àbàmẹ́ta wípé ibà ìrẹ̀lẹ̀ tí gbogbo wa mọ̀ sí Lassa Fever tún ti ṣẹ́ yọ ní ìpínlẹ̀ náà.

Komíṣọ́nà náà sọ wípé arákùnrin kan tí ó jẹ́ ọmọ ogójì ọdún ni ó ní àrùn náà, ó ní àwọn ti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ ẹtì ọjọ́ kankànlélógún oṣù kejì ọdún yìí.

Wọ́n ní arákùnrin náà wà ní ilé ìwòsàn ńlá ti ilé ìwé gíga ti ìjọba àpapọ̀ tí ó wà ní Zaria ní ìpínlẹ̀ náà, ìyẹn Ahmadu Bello University Teaching Hospital níbi tí ó ti ń gbá ìtọ́jú lọ́wọ́ lọ́wọ́.