Categories
Ìròyìn

Ilé Ẹjọ́ Sọ Olùkọ́ Tẹ́lẹ̀ Rìí Ní Ilé Ìwé Gíga Ti Ìjọba Àpapọ̀ Ní Ìpínlẹ̀ Èkó Sí Ẹ̀wọ̀n Ọdún Mọ́kànlélógún Lórí Ẹ̀sùn Ìfipábánilòpọ̀

YBTC News Yoruba—Ilé ẹjọ́ gíga tí ó wà ní ìpínlẹ̀ Èkó ní ọjọ́ ọjọ́bọ ti sọ olùkọ́ tẹ́lẹ̀ rí kan ní ilé ìwé gíga ti ìjọba àpapọ̀ tí ó wà ní ìpínlẹ̀ Èkó, ìyẹn University of Lagos sí ẹ̀wọ̀n ọdún Mọ́kànlélógún Lórí ẹ̀sùn Ìfipábánilòpọ̀ pẹ̀lú ọmọ ọdún méjìdínlógún.

Adájọ́ Josephine Oyefeso, nígbà tí ó ń ṣe ìdájọ́ Akin Baruwa, ó ṣe àpèjúwe ìwà náà gẹ́gẹ́bi ìwà ẹranko tí kò sì bójú mu ní àárín àwùjọ wa.

Oyefeso wá sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ wípé eléyìí majẹ́ ẹ̀kọ́ fún gbogbo ènìyàn tí ó ní èròǹgbà ìwà burúkú bẹ́ẹ̀ lọ́kàn.