Categories
Eré Ìdárayà

Akọ́ni-Mọ̀ọ́gbá Ikọ̀ Manchester United Ṣàlàyé Ẹ̀bùn Méjì Tí Ighalo Ní

Akọ́ni-Mọ̀ọ́gbá Ikọ̀ Manchester United ní orílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì, ìyẹn Ole Gunnar Solskjaer ti ṣàlàyé ẹ̀bùn méjì tí ó tayọ tí agbábọ́ọ̀lú tuntun fún ikọ̀ ọ̀ún ní lára.

Akọ́ni-Mọ̀ọ́gbá náà ni a gbọ́ wípé ó ń ṣàlàyé àwọn ẹ̀bùn àmúyẹ náà nígbà tí ó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ kí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ ọjọ́rú.

Nínú ọ̀rọ̀ tí Ikọ̀ Manchester United fi sí orí ẹ̀rọ alátagbà wọn ìyẹn Twitter, wọ́n Ighalo jẹ́ agbábọ́ọ̀lú tí ó da ní ipò iwájú, tí ó sì jẹ́ ọlọ́pọlọ pípé, Agbábọ́ọ̀lù tí ó mọ ǹkan tí ń ṣe.