Categories
Ìròyìn

A Ò Lè Ma Pèsè Owó Irànwọ́ Fún Iná Ọba Mọ́, Ìjọba Àpapọ̀

Ìjọba Àpapọ̀ orílẹ̀ èdè yìí ti sọ ní ọjọ́ ọjọ́rú wípé òun yóò dá wọ́ dúró lórí owó irànwọ́ tí òun ń pèsè fún ìpèsè iná ọba ní ẹ̀ka ètò agbára ní orílẹ̀ èdè yìí.

Ó ké sí Àjọ tí ó ń pèsè iná ọba ní orílẹ̀ èdè yìí wípé kí ó wá ǹkan ṣe sí ìpèsè iná ọba ní ilẹ̀ yìí àti ọ̀nà ìpawó wọlé rẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ kọ̀ọ́, Ìjọba yóò ma ṣe kòkáàirí ọ̀rọ̀ iná ọba ní orílẹ̀ èdè yìí.

Mínísítà fún ọ̀rọ̀ iná ọba àti ọ̀rọ̀ agbára sọ̀rọ̀ yìí ní ọjọ́ ọjọ́rú lẹ́hìn ìpàdé àwọn aláṣẹ orílẹ̀ èdè yìí tí wípé ètò tí ń lọ báyìí láti yanjú àwọn kú díẹ̀ ku díẹ̀ tó ń kojú ẹ̀ka náà.