Categories
Ìròyìn

Ìdí Rèé Tí Ààrẹ Muhammadu Buhari Kò Ṣe Tíì Jáwe Gbéléẹ Lé Àwọn Olórí Jagunjagun Lọ́wọ́ – Ilé Iṣẹ́ Ààrẹ Tún Sọ̀míì

YBTC News Yorùbá- Ilé iṣẹ́ Ààrẹ ilẹ̀ yìí ní ọjọ́ ìṣẹ́gun tún bu ata àti iyọ̀ sí awuyewuye tí ó ń jà rọ̀ìnrọ̀ìn lórí pípé tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Nàìjíríà ńpè wípé kí Ààrẹ Muhammadu Buhari yọ àwọn olórí jagunjagun ilẹ̀ yìí kúrò nítorí wọn ká jú òṣùwọ̀n tóò.

Ilé iṣẹ́ Ààrẹ múlele wípé àsìkò láti yọ àwọn olórí jagunjagun náà nípò àti wípé ó ní àwọn ìgbésẹ̀ kàn ǹ kan tí ilé iṣẹ́ Ààrẹ gbúdọ̀ tẹ́lẹ̀, ilé iṣẹ́ Ààrẹ ní tí àsìkò bá tó, àwọn yóò tẹ́lẹ̀ àwọn ìgbésẹ̀ náà.

Akọ̀wẹ́ àgbà fún ìjọba àpapọ̀, ìyẹn Boss Mustapha ṣí aṣọ lójú ọ̀rọ̀ yìí ní olú ìlú wa Abuja ní ọjọ́ ìṣẹ́gun níbi ìfilọ́lẹ̀ ìwé kan.