Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Ilé Ẹjọ́ Pàṣẹ Pé Kí Wọ́n Fi Ọwọ́ Ṣù kún Òfin Mú Ọ̀gá Àgbà Aṣọ́bodè Tẹ́lẹ̀ Rí Ní Orílẹ̀ Èdè Yìí

YBTC News Yorùbá- Ilé ẹjọ́ gíga ti ìjọba àpapọ̀ tí ó fìdí kalẹ̀ sí Abuja ti pàṣẹ pé kí wọ́n lọ fi ọwọ́ ṣù kún òfin mú Ọ̀gá Àgbà tẹ́lẹ̀ rí ní ilé iṣẹ́ aṣọ́bodè ilẹ̀ yìí, ìyẹn Nigerian Customs Service, Ọ̀gágun Abdullahi Dikko.

Adájọ́ Ijeoma Ojukwu pàṣẹ wípé kí wọ́n lọ mú Dikko látàrí bí ó ṣe kùnà láti yọjú sí ilé ẹjọ́ láti wá jẹ́ jọ́ lórí ẹ̀sùn Ìkówójẹ tí wọ́n kàn án, òun àti àwọn méjì mìíràn. Àjọ tí ó rí sí ìṣe owó ìlú mákumàku nílẹ̀ yìí, ìyẹn ICPC ló fi ẹ̀sùn kàn wọ́n.

Adájọ́ náà nínú Ìdájọ́ rẹ̀ kò já lẹ̀ láti gba ọ̀rọ̀ agbẹjọ́rò Dikko tí ó ń ṣàlàyé wípé Dikko ń ṣàárẹ̀, tí ó sì wà ní ilé ìwòsàn ní ìlú London, ní orílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì lọ́ùń.