Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ogun Buwọ́lu Ìdásílẹ̀ Àmọ̀tẹ́kùn

YBTC Yorùbá- Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ogun ti buwọ́lu ìdásílẹ̀ Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò tí gbogbo àwọn gómìnà ìwọ oòrùn gúúsù panupọ̀ láti ṣe ìdásílẹ̀ rẹ̀.

Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò agbègbè tí amọ̀sí Àmọ̀tẹ́kùn ni ìjọba ìpínlẹ̀ náà ṣe ìbuwọ́lu rẹ̀ ní ibi ìjókòó àwọn aláṣẹ nílé ìjọba ìpínlẹ̀ náà tí ó wà ní Òkè Mosàn, ní olú ìlú ìpínlẹ̀ náà, ìyẹn Abeokuta.

Agbẹnusọ fún ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun lórí ọ̀rọ̀ iroyin, ìyẹn Kunle Somorin tí ó sọ̀rọ̀ yìí fún àwọn oníròyìn ní ọjọ́ ọjọ́rú sọ wípé ìbuwọ́lù náà lẹ́yìn ìjíròrò tí àwọn aláṣẹ nílé ìjọba ṣe, ó ní fún bi wákàtí mẹ́wàá ni àwọn fi ṣe ìpàdé náà.