Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Ààrẹ Muhammadu Buhari Ṣe Ìbẹ̀wò Sí Ìlú Maiduguri Lórí Ọgbọ̀n Èèyàn Tí Boko Haram Pa

YBTC Yorùbá- Ààrẹ Muhammadu Buhari ṣe ìbẹ̀wò sí ìlú Maiduguri ní ìpínlẹ̀ Bornu láti bá àwọn ará ìpínlẹ̀ náà kẹ́dùn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ afẹ̀míṣòfò tí àwọn ẹgbẹ́ afẹ̀míṣòfò alákatakítí ẹ̀sìn Boko Haram ṣe ní ìlú náà láìpẹ́ yìí.

Níbi ìkọlù tí àwọn ẹgbẹ́ afẹ̀míṣòfò alákatakítí ẹ̀sìn Boko Haram náà ṣe, èèyàn ọgbọ̀n ni ó fẹ̀mí ṣòfò.

Ààrẹ Buhari balẹ̀ gùlẹ̀ sí ìlú Maiduguri ní ǹkan bi ago méjìlá ọ̀sán ni ọkọ bàálù Ààrẹ balẹ̀ sí ìlú Maiduguri láti orílẹ̀ èdè Ethiopia níbi tí ó ti ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ìpàdé pẹ̀lú àwọn olórí orílẹ̀ èdè ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú.