Categories
Ìròyìn

Àwọn Gómìnà Ìwọ̀ Oòrùn Gúúsù Ilẹ̀ Nàìjíríà Ń Gbèrò Láti Kọ̀wẹ́ Sí Ọ̀gá Àgbà Ọlọ́pàá Ilẹ̀ Yìí Lóri Bí Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Àmọ̀tẹ́kùn Yóò Ṣe Ma Lo Ìbọn

YBTC Yorùbá- Òye tí ń fojú hàn báyìí wípé àwọn ilé Aṣòfin ìpínlẹ̀ ìwọ̀ oòrùn gúúsù ilẹ̀ yìí yóò jókòó ṣe àgbéyẹ̀wò òfin ìdásílẹ̀ Àmọ̀tẹ́kùn ní ìpínlẹ̀ kóowa wọn ní ọjọ́ ọjọ́ ọjọ́rú.

A tún gbọ́ wípé àwọn Aṣòfin náà yóò ṣe àgbékalẹ̀ Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò míì tí yóò ma ṣe àbójútó Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Àmọ̀tẹ́kùn ní ìpínlẹ̀ kànkan.

Amòfin Àgbà ní ìpínlẹ̀ Ondo, Kola Olawoye sọ wípé lẹ́yìn tí àwọn Aṣòfin náà bá buwọ́lu òfin na, ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan yóò kọ̀wẹ́ sí Ọ̀gá Ọlọ́pàá yányán ilẹ̀ yìí, ìyẹn Mohammed Adamu láti gbàwé àṣẹ fún Ẹ̀ṣọ́ Àmọ̀tẹ́kùn láti máa lo ìbọn.