Categories
Eré Ìdárayà

Ancelotti Ní Ikọ̀ Everton Nírètí Láti Kópa Nínú Ìdíje Europa Líígì Lẹ́yìn Tí Ikọ̀ Náà Fẹ̀yìn Crystal Palace Gbolẹ̀ Yánayàna

YBTC Yorùbá- Ipò Ikọ̀ Everton sún sókè lọsí ipò keje nínú líígì ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì bí Ikọ̀ náà ṣe fẹ̀yìn Crystal Palace gbolẹ̀ yánayàna ní ọjọ́ àbàmẹ́ta, ayò mẹ́ta sí ẹyọkan ni Everton fi fi àgbà han Ikọ̀ ọ̀ún.

Bernard, Richarlison, àti Dominic Calvert-Lewin ni ó gbá àwọn bọ́ọ́lù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọn nú àwọn fún ikọ̀ Everton. Láti ìgbà tí Akọ́ni-Mọ̀ọ́gbá Carlo Ancelotti ti gbaṣẹ́ Ikọ̀ ọ̀ún, ó ti borí ìfẹ̀sẹ̀wọnsẹ̀ márùn-ún, tí ó sì ta ọ̀ọ̀mì méjì nínú ìfẹ̀sẹ̀wọnsẹ̀ tí ó ti gbá ní líígì náà

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn ìfẹ̀sẹ̀wọnsẹ̀ náà, Carlo Ancelotti ní ikọ̀ náà tí ń ṣe gudugudu méje àti yàyà mẹ́fà, ó ní ní báyìí, Ikọ̀ náà nírètí àti kó pa nínú ìdíje Europa ní sáà tó ń bọ̀.