Categories
Ìròyìn

Wàhálà Bẹ́ Sílẹ̀ Ní Iyana Ipaja Bí Ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó Ṣe Fòfin De Ọ̀kadà àti Márúwá

YBTC Yorùbá-Wàhálà, hílàhílo, àti ìjọ̀gbọ̀n bẹ́ sílẹ̀ ní Iyana Ipaja bí àwọn ènìyàn ṣe ń fẹ̀nùhùn hàn lórí bí ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ṣe fòfin de Ọ̀kadà alùpùpù àti kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́ta ní àwọn ojú pópó kan ní ìpínlẹ̀ Èkó.

Nínú fọ́nrán tí wọ́n fi sí orí ẹ̀rọ alátagbà, ó hàn gba ngba wipe inúfu àyàfu ni àwọn ènìyàn náà wà, bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ṣe ń sá àsálà fún èmi ara wọn.

Àwọn tí wọ́n ń ṣe ìfẹ̀núhún hàn náà dáná sí ojú pópó nígbà tí àwọn ènìyàn kò sì lè ṣiṣẹ́ kárakára wọn mọ́.

Ẹni tí ọ̀rọ̀ náà ṣojú rẹ̀ sọ wípé kòṣẹkòṣẹ ni ọta ìbọn ń rọ̀ ní agbègbè náà nítorí àwọn tí wọ́n ń fẹ̀núhún hàn náà ti gbẹ́ná wojú àwọn Ẹ̀ṣọ́ ìjọba tí ó wà ní agbègbè náà.