Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Jonathan Farahàn Ní Aso Rock, Ó Ṣe Ìpàdé Bòńkẹ́lẹ́ Pẹ̀lú Ààrẹ Muhammadu Buhari

YBTC Yorùbá-Ààrẹ àná ní orílẹ̀ èdè yìí, Ọmọwé Goodluck Jonathan ni ó ṣà déédéé yọjú sí ilé ńlá ti ìjọba àpapọ̀ tí a mọ̀ sí Aso Rock ní olú ìlú wa Abuja ní ọjọ́ ọjọ́bọ, tí ó sì ṣe ìpàdé ráḿpẹ́ pẹ̀lú Ààrẹ Muhammadu Buhari.

Ìròyìn fidi rẹ̀ múlẹ̀ wípé Ààrẹ àná náà ṣe ìpàdé bòńkẹ́lẹ́ pẹ̀lú Ààrẹ Muhammadu Buhari. Ìpàdé náà wáyé láàárín ìṣẹ́jú mẹ́wàá.

A gbọ́ wípé ẹnìkankan kò lè ṣàlàyé ǹkan tí ìpàdé àwọn olórí méjèèjì náà dá lé lórí ṣùgbọ́n awuyewuye fojú hàn wípé Jonathan wá kí Buhari lórí ẹ̀ṣọ́ aláàbò tí Ìjọba àpapọ̀ pèsè fún lórí ìkọlù tí àwọn Agbé’bọnrìn kọlu ilé rẹ̀ ní ìlú abínibí rẹ̀.